Àwọn oúnjẹ tó yẹ kí o jẹ àti àwọn tí o gbọ́dọ̀ yàgò fún lásìkò Ramadan

Three people at an iftar table

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Aje, ọjọ kọkanlan, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni awẹ Ramadan ọdun 2024 yoo bẹrẹ fun gbogbo awọn Musulumi kaakiri agbaye.

Awẹ naa ni wọn fi n ṣaami asiko ti Ọlọrun sọ Quran kalẹ fun Anọbi Muhammad.

Awẹ naa jẹ ọkan gboogi lara awọn opo marunn un to so ẹsin Islam ro, o ṣi jẹ dandan fun gbogbo Musulumi lati kopa ninu rẹ, ayaafi awọn to n ṣaarẹ.

Lasiko awẹ ọhun, awọn Musulumi yoo jẹun ni afẹmọju, eyi ti wọn n pe ni ‘suhoor’ tabi ‘sehri.’

Wọn kii jẹun tabi mu omi lasiko awẹ naa titi di igba ti wọn yoo ṣinu ni irọlẹ.

Irufẹ awọn ounjẹ wo lo yẹ ki Musulumi to gba awẹ ninu oṣu Ramadan maa jẹ?

Irufẹ ounjẹ to yẹ ki o maa jẹ lasiko suhoor

Suhoor jẹ asiko ti eeyan n mura lati bẹrẹ oojọ rẹ, o si tọ ki eeyan jẹ ounjẹ to yẹ fun asiko naa.

Onimọ nipa ounjẹ, Ismet Tamer sọ pe “ounjẹ to ni eroja protein, carbohydrates, vitamins, ati minerals lo yẹ ki eeyan maa jẹ ki ara ẹni to n gba awẹ le ni okun.

Tamer gba awọn to n gba awẹ nimọran lati ma ṣe jẹ ounjẹ to wuwo ju.

A man and a woman drinking water

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O fi kun pe wọn le mu miliiki pẹlu awọn nnkan bii ẹyin, kukumba, ati awọn eso oriṣiriṣi.

Ẹlomiran to tun jẹ onimọ nipa ounjẹ, Bridget Benelam sọ pe awọn ounjẹ to ni eroja ‘carbohydrate’ dara pupọ lasiko awẹ.

Bẹẹ naa lo tun ṣalaye pe ki wọn si mu awọn ohun mimu to wa lati ara eso nitori wọn n ṣe ara loore.

Ohun to yẹ ki o jẹ lẹyin iftar

Awọn onimọ sọ pe o tọ ki awọn to n gbaawẹ jẹ ọpọlọpọ eso ti wọn ba n ṣinu.

Bridget Benelam sọ pe jijẹ eso ‘date’, ti awọn kan tun n pe ni ''Dabino' ni Naijiria, ati ọpọlọpọ omi dara lati kọkọ ṣinu.

A bowl of dates

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Benelam ni “lẹin ọpọ wakati ti o ko tii jẹun, ko tọ lati ku giri jẹ ounjẹ to wuwo.

Awọn onimọ nipa ounjẹ mii fun awọn to n gbaawẹ nimọran lati pin ounjẹ iftar wọn si meji, ki wọn jẹ ẹ tẹle ara wọn laarin akoko diẹ sira wọn, dipo ki wọn jẹ ounjẹ pupọ lẹẹkan ṣoṣo.

Iftar table

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ, awọn onimọ nipa ounjẹ ti fẹnuko pe o dara lati maa gbaawẹ nitori awọn anfaani rẹ pọ fun agọ ara.

Lara awọn anfaani naa ni pe yoo ṣoro fun ẹni to ba n gbaawẹ lati sanra ju bo ṣe yẹ lọ.